You are here

Ìròyìn bí a ti máa ń kírun

×

Error message

Deprecated function: Function create_function() is deprecated in views_php_handler_field->pre_render() (line 202 of /var/www/drupal7-websites/sites/all/modules/contrib/views_php/plugins/views/views_php_handler_field.inc).

 1. Àníyàn:

Àníyàn jẹ́ májẹ̀mu fún níní àlááfìà ìrun, èyí túmọ̀ sí kí ẹni tí ó ń kírun ní àdìsọ́kàn pé òun ń jọ́sìn fún Ọlọ́hun pẹ̀lú ìrun kíkí, tí yóò tún mọ̀, ní àpèjúwe, pé ìrun àṣálẹ́ ni tàbí ìrun alẹ́. Sísọ àníyàn jáde kò bá òfin ẹ̀sìn Islām mú, ṣùgbọ́n èròńgbà ọkàn àti làákàyè ni ohun tí a fẹ́. Sísọ ọ́ jáde  kò wá láti ọ̀dọ̀ Ànábì -kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a- àti àwọn sàábé rẹ̀ alápọ̀n-ọ́nlé.  

 1. Yóò dìde dúró láti kírun, yóò sì wí pé:

(Allāhu ’Akbar: Ọlọ́hun ni Ó tóbi jùlọ). Yóò sí gbé ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì sókè dé etí rẹ̀ méjèèjì tàbí èjìká  rẹ̀  méjèèjì, ní ẹni tí ó kọ̀ inú  ọwọ́ rẹ̀ sí gábàsì.
Gbígbé Ọlọ́hun tóbi kò ní ẹ̀tọ́ àyàfi pẹ̀lú gbólóhùn yìí (Allāhu ’Akbaru: Ọlọ́hun ni Ó tóbi jùlọ). Ìtumọ̀ rẹ̀ ni gbígbé tóbi àti fífan rere gbígbọngbọ́ Ọlọ́hun. Ọlọ́hun ni Ó tóbi jù gbogbo ohun tí ó yàtọ̀ sí I lọ. Ó tóbi jù ayé àti gbogbo adùn àti ìgbádùn tí ó wà nínú rẹ̀ lọ. Nítorí náà kí a yáa ju gbogbo ìgbádùn sí ẹ̀gbẹ́ kan, kí á sì dojú kọ Ọlọ́hun, Ọba tí Ó tóbi, Ọba Giga lórí ìrun pẹ̀lú ọkàn wa àti làákàyè wa ní ẹni tí ó ń páyà Rẹ̀.    

 1. Lẹ́yìn gbígbé Ọlọ́hun tóbi, yóò gbé ọwọ́ rẹ̀ ọ̀tún lé ọwọ́ rẹ̀ òsì yóò máa ṣe èyí ní gbogbo ìgbà tí ó bá ti wá ní ìnàró lórí ìrun. 
 1. Yóò ṣe àdúrà ìbẹ̀rẹ̀ ìrun, ní ohun tí a fẹ́, pé: (Subḥānaka Allāhumma wabiḥamdika watabārakas-muka wata‘ālā jadduka walā ’ilāha ghayruk): Mímọ́ ni fún Ọ, Ìrẹ Ọlọ́hun, mo tún ṣe ọpẹ́ àti ẹyìn fún Ọ. Ìbùkún ni fún Orúkọ́ Rẹ, gíga sì ni fún Títóbi Rẹ. Kò sí ọlọ́hun kan tí ó lẹ́tọ̀ọ́ sí ìjọsìn lẹ́yìn Rẹ.
 1. Yóò sọ pé: (’A‘ūdhu billāhi minash-shayṭānir-rajīm): {Mo wá ìṣọ́ pẹ̀lú Ọlọ́hun kúrò lọ́dọ̀ èṣù, ẹni tí a ti gbé jìnnà sí àánú Ọlọ́hun}. Èyí ni ìwáṣọ́ọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́hun, ìtumọ̀  rẹ̀ ni: Mò ń wá ìsádi, mò sì ń wá ìṣọ́ pẹ̀lú Ọlọ́hun kúrò níbi aburú èṣù.   
 1. Yóò sọ pé: (Bismillāhir-Raḥmānir-Raḥīm): {(Mo bẹ̀rẹ̀) pẹ̀lú Orúkọ Ọlọ́hun Allāh, Ọba Àjọkẹ́ Ayé, Ọba Àṣàkẹ́ Ọ̀run}. Ìtumọ̀ rẹ̀ ni: Mo bẹ̀rẹ̀ ní ẹni tí ó ń wá ìrànlọ́wọ́  Ọlọ́hun,  ní ẹni tí ó ń tọrọ ìbùkún  pẹ̀lú Orúkọ Rẹ̀.    
 1. Yóò ké Sūratul-Fātiḥah, Fātiḥah sì ni ọgbà-ọ̀rọ̀ tí ó tóbi lọ́lá jùlọ nínú Tírà Ọlọ́hun.
 • Dájúdájú Ọlọ́hun fi sísọ̀ ọ́ kalẹ̀ ṣe ìrègún lórí Ìránṣẹ́ Rẹ̀, Ó wí pé: “Àti pé dájúdájú A ti fún ọ ní (āyah) méje nínú oníméjìméjì àti Al-Qur’ān tí ó tóbi” (Al-Ḥijr: 87). (Āyah) méje oníméjìméjì ni Fātiḥah. Wọ́n sọ ọ́ bẹ́ẹ̀, nítorí pé ó jẹ́ āyah méje tí àwọn ènìyàn máa ń pààrà rẹ̀ ní ojoojúmọ́.    
 • Ó ṣe ọ̀ranyàn fún Mùsùlùmí kí ó kọ́ ọ; nítorí pé dandan ní kíké e ní orí ìrun, fún ẹni tí ń síwájú kírun fún àwọn ènìyàn àti ẹni tí ó ń dá ìrun kí, ẹni tí ń kírun lẹ́yìn Imām náà yóò ké e níbi ìrun tí Imām kò bá ti kéwú sókè. 
 1. Wọ́n ṣe é ní òfin fún un, lẹ́yìn kíké Fātiḥah tàbí gbígbọ́ ọ, kí ó sọ pé: (Āmīn), Ìtumọ̀ rẹ̀ ni: Ìrẹ  Ọlọ́hun! Gba àdúrà wa.
 1. Lẹ́yìn kíké Fātiḥah; yóò ké, níbi òpó-ìrun méjì àkọ́kọ́, ọgbà-ọ̀rọ̀ (sūrah) Al-Qur’ān mìíràn tàbí àwọn ẹsẹ-ọ̀rọ̀ (āyah) Al-Qur’ān láti inú ọgbà-ọ̀rọ̀ Al-Qur’ān mìíràn, ṣùgbọ́n níbi òpó-ìrun kẹta àti ìkẹrin,  Fātiḥah nìkan ni yóò ké
 • Kíké Fātiḥah àti ohun tí a ó ké lẹ́yìn rẹ̀, yóò jẹ́ kíké sókè níbi ìrun àfẹ̀rẹ̀mọ́júmọ́, àṣálẹ́ àti alẹ́, yóò sì jẹ́ kíké jẹ́ẹ́jẹ́ níbi ìrun ọ̀sán àti ìrọ̀lẹ́.
 • Ṣùgbọ́n gbogbo ìrántí Ọlọ́hun, èyí tí ó ṣẹ́kù lórí ìrun, jẹ́ẹ́jẹ́ ni a máa ń sọ ọ́.

 1. Lẹ́yìn náà yóò gbé Ọlọ́hun tóbi fún rúkúù (títẹ̀ kọ̀kọ̀rọ̀), ní ẹni tí ó  gbé ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì dé etí rẹ̀ méjèèjì tàbí èjìká rẹ̀ méjèèjì, ní ẹni tí ó kọ̀ inú àtẹ́lọwọ́ rẹ̀ sí gábàsì, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe níbi gbígbé  Ọlọ́hun tóbi àkọ́kọ́. 
 1. Yóò rúkúù

(yóò tẹ̀ kọ̀kọ̀rọ̀) pẹ̀lú pé kí ó tẹ ẹ̀yìn rẹ̀ ba sí agbegbe gábàsì, ẹ̀yìn rẹ̀ àti orí rẹ̀ yóò sì ṣe déédé ara wọn, yóò sì gbé ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì lé orúnkun rẹ̀ méjèèjì, yóò sì wí pé: (Subḥāna Rabbiyal-‘Aẓīm) {Mímọ́ ni fún Ọlọ́hun Ọba mi, Ọba tí Ó tóbi}.  Wọ́n sì fẹ́ kí á pààrà ṣíṣe àfọ̀mọ́ fún Ọlọ́hun ní ẹ̀ẹ̀mẹta,.. títẹ̀ kọ̀kọ̀rọ̀ (rukū‘) jẹ́ ààyè ìgbé-Ọlọ́hun tóbi àti fífan rere gbígbọngbọ́ Ọlọ́hun, Ọba tí Ọlá Rẹ̀ ga.     

Ìtumọ̀ (Subḥāna Rabbiyal-‘Aẓīm): ni pé mò ń fọ Ọlọ́hun, Ọba tí Ó tóbi, mọ́, mo sì ń ṣe àfọ̀mọ́ fún Un kúrò níbi gbogbo àbùkù, mò ń sọ ọ́ nígbà tí mò ń tẹ̀ kọ̀kọ̀rọ̀, tí mo sì ń tẹríba fún  Ọlọ́hun,  Ọba Abiyì, tí Ó gbọn-n-gbọ́n. 

 1. Yóò gbé orí sókè láti rúkúù 

padà sí ìnàró, ní ẹni tí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì sókè sí déédé èjìká rẹ̀ méjèèjì, yóò sì kọ inú méjèèjì sí agbegbe gábàsì, gẹ́gẹ́ bí ó ti síwájú, yóò sì wí pé: (Sami‘allāhu liman ḥamidah). {Ọlọ́hun gbọ ẹyìn ẹni tí ó yìn Ìn}. Tí ó bá jẹ́ Imām tàbí ó jẹ́ ẹni tí ó ń dá ìrun kí. Lẹ́yìn náà gbogbo wọn yóò wí pé: (Rabbanā walakal-ḥamd). {Ìrẹ Ọlọ́hun Ọba wa! Gbogbo ọpẹ́ àti ẹyìn tì Ẹ ní í ṣe}.  Wọ́n fẹ́ kí ó fi kún un, kí ó wí lẹ́yìn rẹ́ pé: (...Ḥamdan kathīran ṭayyiban mubārakan fīh, mil’as-samā’i wamil’al-’arḍ, wamā baynahumā, wamil’a mā shi’ta min shay’in ba‘d).  {Ní ẹyìn tí ó pọ̀, tí ó dára, tí a fi ìbùkún sí i. (Ní ẹyìn) tí ó kún sánmà àti ilẹ̀ àti ohun tí ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì, tí ó tún kún ohunkóhun tí O fẹ́ lẹ́yìn náà}.        

 1. Lẹ́yìn èyí, yóò lọ sílẹ̀

ní ẹni tí ó ń gbé Ọlọ́hun tóbi, yóò sì fi orí kanlẹ̀ lórí àwọn oríkèé rẹ̀ méjèèje, èyí ni: Iwájú-orí pẹ̀lú imú, ọwọ́ méjèèjì, orúnkun méjèèjì àti gìgísẹ̀ méjèèjì. A sì fẹ́ kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì jìnnà sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ méjèèjì, kí ó sì gbé inú rẹ̀ jìnnà sí itan rẹ̀ méjèèjì, kí ó tún gbé itan rẹ̀ méjèèjì jìnnà sí ẹsẹ̀ rẹ̀  méjèèjì ní ìforíkanlẹ̀, kí ó sì gbé ìgbọ̀nwọ́ rẹ̀ kúrò lórí ilẹ̀.   

 1. Yóò sọ, ní ìforíkanlẹ̀ rẹ̀, pé: 

 (Subḥāna Rabbiyal-’A‘lā) ,  {Mímọ́ ni fún Ọlọ́hun Ọba mi, Ọba tí Ó ga jùlọ}. Wọ́n sì fẹ́ kí ó pààrà rẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀mẹta. 
Ìtumọ̀ (Subḥāna Rabbiyal-’A‘lā): Mò ń fọ  Ọlọ́hun mọ́, Ọba tí Ó ga jùlọ níbi Títóbi Rẹ̀ àti Pípàtàkì Rẹ̀, Ọba tí Ó ga jùlọ ní òkè àwọn sánmà Rẹ́ kúrò níbi gbogbo àbùkù àti àléébù. Ìtanijí ń bẹ níbẹ̀ fún ẹni tí ó fi orí kanlẹ̀, tí ó fi orí lélẹ̀ níti ìtẹríba àti ìyẹpẹrẹ ara ẹni fún Ọlọ́hun, kí ó le rántí ìyàtọ̀ láàrin rẹ̀ àti láàrin Aṣẹ̀dá rẹ̀,  Ọba tí Ó ga jùlọ, nítorí kí ó le rọ ara rẹ̀ nílẹ̀ fún  Ọlọ́hun  Ọba rẹ̀, kí ó sì tẹríba fún Olùgbọ̀wọ́ rẹ̀.  

Ìforíkanlẹ̀ ń bẹ lára àwọn ààyè bíbẹ  Ọlọ́hun, Ọba Abiyì, tí Ó gbọn-n-gbọ́n, Mùsùlùmí yóò bẹ Ọlọ́hun níbẹ̀ lẹ́yìn ìrántí  Ọlọ́hun tí ó ṣe ọ̀ranyàn pẹ̀lú ohun tí ó bá fẹ́ nínú oore ayé àti Ọ̀run, Ànábì -kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a- wí pé: “Ìgbà tí ẹrúsìn Ọlọ́hun súnmọ́ Ọlọ́hun, Ọba rẹ̀ jùlọ ni ìgbà tí ó bá wà ní ìforíkanlẹ̀, nítorí náà ẹ ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àdúrà níbẹ̀” (Muslim: 482).

 1. Lẹ́yìn náà yóò sọ pé: 

(Allāhu ’Akbaru: Ọlọ́hun ni Ó tóbi jùlọ), yóò sì jókòó láàrin ìforíkanlẹ̀ méjèèjì, a sì fẹ́ kí ó jókòó lé àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀ òsì, kí ó sì nàró ọ̀tún, yóò sì gbé ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì lé ìbẹ̀rẹ̀ itan rẹ̀ méjèèjì níbi tí ó súnmọ́ orúnkún rẹ̀ méjèèjì.  

 • Gbogbo ìjókòó orí ìrun ni a fẹ́ ìlànà  ìjókòó yìí níbẹ̀, àyàfi níbi àtááyá ẹlẹ́ẹ́kejì, ó ṣeéṣe fún un, pẹ̀lú èyí, kí ó nàró  àtẹ́lẹsẹ̀ ọ̀tún bákan náà, ṣùgbọ́n yóò yọ ẹsẹ̀ òsì síta láti abẹ́ rẹ̀, yóò sì fi ìdí lélẹ̀.
 1. Yóò sọ níbi ìjkòó rẹ̀ láàrin ìforíkanlẹ̀ méjèèjì pé: (Rabbighfir lī: Ìrẹ Ọlọ́hun Ọba mi! Forí jìn mí). A sì fẹ́ kí ó pààrà rẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀mẹta. 
 1. Lẹ́yìn náà yóò fi orí kanlẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀kejì gẹ́gẹ́ bíi ìforíkanlẹ̀ rẹ̀ àkọ́kọ́.
 1. Lẹ́yìn náà yóò dìde láti ibi ìforíkanlẹ̀  kejì lọ sí ìnàró ní ẹni tí ó sọ pé (Allāhu ’Akbaru: Ọlọ́hun ni Ó tóbi jùlọ).
 1. Yóò kí òpò-ìrun kejì gẹ́gẹ́ bíi ti  àkọ́kọ́ gẹ́lẹ́.
 1. Lẹ́yìn ìforíkanlẹ̀ rẹ̀ kejì 

níbi òpó-ìrun kejì, yóò jókòó fún àtááyá alákọ̀kọ́ọ́,  yóò wí pé: (At-taḥiyyātu lillāhi waṣ-ṣalawātu waṭ-ṭayyibāt, as-salāmu ‘alayka ’ayyuhan-nabiyyu waraḥmatullāhi wabarakātuh, as-salāmu ‘alaynā wa‘alā ‘ibādillāhiṣ-ṣālihīn. ’Ashhadu ’an lā ’ilāha ’illallāh, wa’ashhadu ’anna Muḥammadan ‘abduhu warasūluh:
Gbogbo kíkí ti Ọlọ́hun ni í ṣe, àti gbogbo ìrun àti gbogbo dáadáa. Àlááfíà Ọlọ́hun kí ó máa bá ọ, ìrẹ Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun, àti ìkẹ́ Ọlọ́hun àti ìbùkún Rẹ̀. Àlááfíà Ọlọ́hun kí ó máa bá wa, kí ó sì máa bá àwọn ẹni dáadáa nínú àwọn ẹrúsìn Ọlọ́hun. Mo jẹ́rìí pé kò sí ọlọ́hun kan tí ó lẹ́tọ̀ọ́ sí ìjọsìn àyàfi Ọlọ́hun Allāh nìkan, mo sì jẹ́rìí pé Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun Muḥammad, níti pàápàá, jẹ́ ẹrúsìn Rẹ̀ àti Ìránṣẹ́ Rẹ̀)

 1. Lẹ́yìn náà yóò dìde

láti kí ìrun rẹ̀ tí ó ṣẹ́kù, tí ìrun náà bá jẹ́ olópòó mẹ́ta tàbí mẹ́riin, yàtọ̀ sí pé kò ní ké ju Fātiḥah nìkan lọ níbi òpó-ìrun kẹta àti ìkẹrin.

 • Ṣùgbọ́n tí ìrun bá jẹ́ olópòó méjì bíi ìrun  Àsùnbáà, dájúdájú yóò ṣe àtááyá ìgbẹ̀yìn gẹ́gẹ́ bí ó ti ń bọ̀.

 1. Lẹ́yìn náà níbi òpó-ìrun ígbẹ̀yìn,  lẹ́yìn ìforíkanlẹ̀  kejì, yóò jókòó fún  àtááyá ìgbẹ̀yìn, 

àlàyé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi àtááyá àkọ́kọ́ ni, pẹ̀lú àlékún àsàlátù fún Ànábì ní ọ̀nà tí ń bọ̀ yìí: (Allāhumma ṣalli ‘alā Muḥammad, wa‘alā ’āli Muḥammad, kamā ṣallayta ‘alā Ibrāhīma wa‘alā ’āli Ibrāhīm, ’innaka Ḥamīdun Majīd, wabārik ‘alā Muhammad, wa‘alā ’āli Muḥammad, kamā bārakta ‘alā Ibrāhīma wa‘alā ’āli Ibrāhīm, ’innaka Ḥamīdun Majīd: Ìrẹ Ọlọ́hun! Ṣe ìkẹ̀ fún (Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun) Muḥammad àti fún àwọn ará ilé Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun Muḥammad gẹ́gẹ́ bí O ti ṣe ìkẹ̀ fún (Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun) Ibrāhīm àti fún àwọn ará ilé (Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun) Ibrāhīm. Dájúdájú Ìwọ ni Ẹni ẹyìn, Ẹni títóbi. Tún ṣe ìbùkún fún (Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun) Muḥammad àti fún àwọn ará ilé (Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun) Muḥammad gẹ́gẹ́ bí O ti ṣe ìbùkún fún (Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun) Ibrāhīm àti fún àwọn ará ilé (Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun) Ibrāhīm. Dájúdájú Ìwọ ni Ẹni ẹyìn, Ẹni títóbi).

 • A sì fẹ́ fún un lẹ́yìn èyí, kí ó wí pé: (Allāhumma ’innī ’a‘ūdhu bika min ‘adhābi jahannam, wamin ‘adhābil-qabr, wamin fitnatil-maḥyā wal-mamāt, wamin fitnatil-masīḥid-dajjāl: Ìrẹ Ọlọ́hun! Dájúdájú èmi ń wá ìṣọ́ pẹ̀lú Rẹ kúrò níbi ìyà iná Jahannam, àti kúrò níbi ìyà inú sàréè, àti kúrò níbi wàhálà ìṣẹ̀mí ayé àti ikú, àti kúrò níbi wàhálà Al-Masīḥ Ad-dajjāl). Kí ó sì tọrọ ohun tí ó bá fẹ́.
 1. Lẹ́yìn náà yóò yíjú sí ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún, yóò sì wí pé:

(As-salāmu ‘alaykum waraḥmatullāh:  Àlááfìà  àti ìkẹ́ Ọlọ́hun kí ó máa bá yín).  Lẹ́yìn náà yóò ṣe bẹ́ẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́ òsí.

Pẹ̀lú sísálámà, Mùsùlùmí ti parí ìrun rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí  Ànábí -kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a- ti wí pé: “Ohun tí ó máa ń sọ̀ ọ́ di ọ̀wọ̀ ni gbígbé Ọlọ́hun tóbi, ohun tí a sì fi máa ń jáde kúrò nínú rẹ̀ ni sísálámà” (Abū Dāwūd: 61, At-Tirmidhī: 3). Ìtumọ̀ èyí ni pé: Dájúdájú ìrun, a máa ń wọnú rẹ̀ pẹ̀lú gbígbé  Ọlọ́hun tóbi àkọ́kọ́, a sì  máa ń jáde kúrò nínú rẹ̀ pẹ̀lú sísálámà.     

 1. Lẹ́yìn  sísálámà, níbi ìrun ọ̀ranyàn, a fẹ́ kí ó wí pé:
 1. (’Astaghfirullāh: Mò ń tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Ọlọ́hun),  ní ẹ̀ẹ̀mẹta.
 2. Yóò tún wí pé: (Allāhumma ’Antas-salām waminkas-salām, tabārakta yā dhal-jalāli wal-’ikrām: Ìrẹ Ọlọ́hun! Ìwọ ni Àlááfíà, ọ̀dọ̀ Rẹ sì ni àlááfíà tí ń wá. Ìbùkún ni fún Ọ, Ìrẹ Ọba tí Ó ni títóbi àti àpọ́nlé), (Allāhumma lā māni‘a limā ’a‘ṭayt, walā mu‘ṭiya limā mana‘t, walā yanfa‘u dhal-jaddi minkal-jadd:  Ìrẹ Ọlọ́hun! Kò sí ẹni tí ó le kọ ohun tí O bá fúnni, kò sì sí ẹni tí ó le fúnni ní ohun tí O bá kọ̀, àti pé ọrọ̀ ọlọ́rọ̀ kò le ṣe é ní àǹfààní ní ọ̀dọ̀ Rẹ).
 3. Lẹ́yìn náà yóò wí pé: (Subḥānallāh: Mímọ́ ni fún Ọlọ́hun), yóò pààrà rẹ̀ nígbà 33, àti (Al-ḥamdu lillāh: Gbogbo ọpẹ́ àti ẹyìn tí  Ọlọ́hun  ní í ṣe)  nígbà 33, àti  (Allāhu ’Akbar:  Ọlọ́hun ni Ó tóbi jùlọ)  nígbà 33. Yóò sì pé ọgọ́rùn-ún pẹ̀lú kí ó wí pé: (lā ’ilāha ’illallāhu waḥdahu lā sharīka lah, lahul-mulku walahul-ḥamd, wahuwa ‘alā kulli shay’in Qadīr:  Kò sí ọlọ́hun tí ó lẹ́tọ̀ọ́ sí ìjọsìn àyàfi Ọlọ́hun Allāh nìkan ṣoṣo, kò sí orogún fún Un. Ti Ẹ̀ ni ìjọba, ti Ẹ̀ sì ni gbogbo ọpẹ́ àti ẹyìn í ṣe, àti pé Òun ni Alágbára lórí gbogbo nǹkan).

Kín ni ohun tí ẹni tí kò bá há Fātiḥah àti àwọn ìrántí Ọlọ́hun orí-ìrun yóò ṣe?

 • Ó ṣe ọ̀ranyàn fún un kí ó há àwọn ìrántí Ọlọ́hun tí ó jẹ́ ọ̀ranyàn lórí ìrun, nítorí pé kò le ní alááfíà àyàfi pẹ̀lú èdè Lárúbáwá,  àwọn  nìyí: 
  Kíké Fātiḥah àti gbígbé Ọlọ́hun tóbi, sísọ pé: Subḥāna Rabbiyal-‘Aẓīm, sami‘allāhu liman ḥamidah, subḥāna Rabbiyal-’A‘lā, Rabbighfir lī, àtááyá, ṣiṣe àsàlátù fún Ànábí àti sísálámà.  
 • Ó ṣe ọ̀ranyàn fún Mùsùlùmí, síwájú kí ó tó há  Fātiḥah tán, kí ó máa pààrà ohun tí ó bá mọ̀ nínú ṣíṣe àfọ̀mọ́ fún Ọlọ́hun,  ṣíṣe ẹyìn fún Un àti gbígbé E tóbi ní orí ìrun tàbí kí ó máa pààrà āyah tí ó há nígbà tí ó bá wà ní ìnàró, gẹ́gẹ́ bí  Ọba tí Ọlá Rẹ̀ ga, ti wí pé: “Nítorí náà ẹ bẹ̀rù Ọlọ́hun bí ẹ bá ti lágbara tó” (At-Taghābun: 16). 
 • Ó pàtàkì fún un, ní àsìkò yìí, kí ó ṣe ojúkòkòrò tí ó pé lórí kíkírun Jamā‘ah pẹ̀lú àkójọpọ̀ àwọn Mùsùlùmí nítorí kí ó le mọ bí yóò ti máa kírun dáadáa, àti  nítorí pé Imām máa ń gbé díẹ̀ nínú àṣeètó ẹni tí ó ń kírun lẹ́yìn rẹ̀.   

Ìtọ́ka Mùsùlùmí tí a ṣe ní ìrọ̀rùn

Ààyè Ìtọ́ka Mùsùlùmí tí a ṣe ní ìrọ̀rùn jẹ́ ẹ̀dà orí ẹ̀rọ ayé-lu-jára láti inú ìwé (Ìtọ́ka Mùsùlùmí tí a ṣe ní ìrọ̀rùn). Ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn iṣẹ ilé-iṣẹ́ ìtọ́ka ìgbàlódé. A sì ti tẹ̀ ẹ́ jáde pẹ̀lú èdè tó ju 15 lọ. A tún ti mú àkóónú rẹ̀ wá lórí ọlọ́kan-ò-jọ̀kan nínú àwọn ìkànnì ẹ̀rọ ayé-lu-jára tó yanrannti

Modern Guide