You are here

Àwọn ìrántí Ọlọ́hun nínú àwọn ìṣesí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀

×

Error message

Deprecated function: Function create_function() is deprecated in views_php_handler_field->pre_render() (line 202 of /var/www/drupal7-websites/sites/all/modules/contrib/views_php/plugins/views/views_php_handler_field.inc).

Àwọn ìrántí Ọlọ́hun ní àárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́

’Āyatul-Kursiyy wo (ojú-ewé 271)

Al-Mu‘awwidhāt wo (ojú-ewé 272)

{Bismillāhil-ladhī lā yaḍurru ma‘asmihi shay’un fil-’arḍi walā fis-samā’i wahuwas-samī‘ul-‘Alīm}

(Mo wá ìṣọ́ra) pẹ̀lú Orúkọ Ọlọ́hun, Ẹni tí ohun kan kò le nini lára pẹ̀lú Orúkọ Rẹ lórí ilẹ̀ àti ní sánmà, àti pé Òun ni Olùgbọ́ gbogbo nǹkan, Olùmọ gbogbo nǹkan. 
Dájúdájú Ànábí -kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a- fún wa ní ìró pé kò sí ẹrúsìn Ọlọ́hun  tí yóò ké e ní àárọ̀ tàbí ní ìrọ̀lẹ́ ní ẹ̀ẹ̀mẹta, tí ohun kan yóò ni í lára (At-Tirmidhī). 

Raḍītu billāhi Rabban, wabil-’Islāmi dīnā, wabiMuḥammadin ṣallal-Lāhu ‘alyhi wasallam nabiyyā}

Mo yọ́nú sí Ọlọ́hun Allāh ní Ọlọ́hun Ọba, sí ẹ̀sìn Islām ní ẹ̀sìn, àti sí Muḥammad -kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a- ní Òjíṣẹ́.
Ànábí -kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a- wí pé: Kò sí ẹrúsìn Ọlọ́hun Mùsùlùmí tí yóò sọ nígbà tí ó bá mọ́jú àti nígbà tí ó bá di ìrọ̀lẹ́, ní ẹ̀ẹ̀mẹta, pé: Raḍītu billāhi Rabbā, wabil-’Islāmi dīnā, wabi Muḥammadin ṣallal-Lāhu ‘alyhi wasallam nabiyyā, àyàfi fi kí ó jẹ́ iwọ̀ fún Ọlọ́hun, ní  ọjọ́ Ìgbéǹde, kí Ó yọ́nú sí i” (Aḥmad: 18967). 

{Allāhumma ’Anta Rabbī lā ’ilāha ’illā ’Ant, khalaqtanī wa’ana ‘abduk, wa’ana ‘alā ‘ahdika wawa‘dika mastaṭa‘t, ’a‘ūdhu bika min sharri mā ṣana‘t, ’abū’u laka bini‘matika ‘alayy, wa’abū’u bidhanbī, faghfir lī fa’innahu lā yaghfirudh-dhunūba ’illā ’Ant}

Ìrẹ Ọlọ́hun! Ìwọ ni Ọlọ́hun Ọba mi, kò sí Ọlọ́hun kan tí ó lẹ́tọ̀ọ́ sí ìjọsìn àyàfi Ìwọ nìkan. O dá mi, àti pé èmi jẹ́ ẹrúsìn fún Ọ. Èmi sì ń bẹ lórí ìpínhùn Rẹ àti àdéhùn Rẹ bí mo ti lágbára mọ. Mo wá ìṣọ́ pẹ̀lú Rẹ kúrò níbi aburú ohun tí mo ṣe. Mo gbà fún Ọ pẹ̀lú ìdẹ̀ra Rẹ tí O se fún mi, mo sì mọ ẹ̀ṣẹ̀ mi ní ẹ̀ṣẹ̀. Nítorí náà ṣe àforíjìn fún mi. Dájúdájú kò sí ẹni tí ó le ṣe àforíjìn àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àyàfi Ìwọ nìkan.
Ànábí -kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a- wí pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ọ́, ní ẹni tí ó gbà á gbọ́ lódodo, tí ó wá kú ní ọjọ́ náà kí ó tó di ìrọ̀lẹ́, yóò wà lára àwọn ara ọgbà-ìdẹ̀ra. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ọ́, ní alẹ́, ní ẹni tí ó gbà á gbọ́ lódodo, tí ó wá kú, kí ó tó mọ́jú, yóò wà lára àwọn ara ọgbà-ìdẹ̀ra” (Al-Bukhārī: 5947).

{’Aṣbaḥnā wa’aṣbaḥal-mulku lillāh wal-ḥamdu lillāh lā ’ilāha ’illallāh, waḥdahu lā sharīka lah, lahul-mulku walahul-ḥamd, wahuwa ‘alā kulli shay’in Qadīr, Rabbi ’as’aluka khayra mā fī hādhal-yawm, wakhayra mā ba‘dah, wa’a‘ūdhu bika min sharri mā fī hādhal-yawm, washarri mā ba‘dah, Rabbi ’a‘ūdhu bika minal-kasal, wasū’il-kibar, Rabbi ’a‘ūdhu bika min ‘adhābin fin-nār, wa‘adhābin fil-qabr} 

A ti jí sáyé, gbogbo ìjọba sì tún jẹ́ ti Ọlọ́hun. Gbogbo ọpẹ́ àti ẹyìn ti Ọlọ́hun nìkan ni í ṣe. Kò sí Ọlọ́hun kan tí ó lẹ́tọ̀ọ́ sí ìjọsìn àyàfi Ọlọ́hun Allāh nìkan ṣoṣo, kò sí orogún fún Un. Ti Ẹ̀ ni ìjọba; ti Ẹ̀ sì ni gbogbo ọpẹ́ àti ẹyìn í ṣe, àti pé Òun ni Alágbára lórí gbogbo nǹkan. Ìrẹ Ọlọ́hun Ọba mi! Mo ń tọrọ oore ọjọ́ òni yìí lọ́dọ̀ Rẹ àti oore ohun tí ń bẹ ní ẹ̀yìn rẹ̀, mo sì ń wá ìṣọ́ pẹ̀lú Rẹ kúrò níbi aburú òni yìí àti aburú ohun tí ń bẹ ní ẹ̀yìn rẹ̀. Ìrẹ Ọlọ́hun Ọba mi! Mo ń wá ìṣọ́ pẹ̀lú Rẹ kúrò níbi òròjú àti aburú ogbó. Ìrẹ Ọlọ́hun Ọba mi! Mo ń wá ìṣọ́ pẹ̀lú Rẹ kúrò níbi ìyà inú iná àti ìyà inú sàréè. (Muslim: 2723).
Nígbà tí ó bá di ìrọ̀lẹ̀ yóò pààrọ̀ àwọn gbólóhùn àárọ̀ pẹ̀lú ìrọ̀lẹ̀. 

Àdúrà tí a máa ń ṣe nìgbà tí a bá fẹ́ jẹun 

Síwájú oúnjẹ

“Nígbà tí ẹnikẹ́ni nínú yín bá fẹ́ jẹ oúnjẹ,  kí ó wí pé: Bismillāh (pẹ̀lú Orúkọ Ọlọ́hun). Tí ó bá gbàgbé ní ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀, kí ó wí pé: Bismillāhi fī ’awwalihi wa’ākhirih (Mo bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú Orúkọ Ọlọ́hun ní ìfáárà rẹ̀ àti ní ìparí rẹ̀)” (At-Tirmidhī: 1858, 3264). 

Nígbà tí a bá parí oúnjẹ 

“Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ oúnjẹ kan, tí ó sì wí pé: {Al-ḥamdu lillāhil-ladhī ’aṭ‘amanī hādhā warazaqanīhi min ghayri ḥawlin minnī walā quwwah} (Gbogbo ọpẹ́ àti ẹyìn ti Ọlọ́hun ni í ṣe, Ẹni tí Ó fún mi ní oúnjẹ yìí jẹ. Tí Ó pese rẹ̀ fún mi láìsí ọgbọ́n kankan, tí kò sì sí agbára kankan lọ́dọ̀ mi). Ọlọ́hun yóò fi orí ohun tí ó síwájú nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jìn ín”  (At-Tirmidhī: 3458, Abū Dāwūd: 4023).

Àdúrà tí a máa ń ṣe nìgbà tí a bá fẹ́ wolé

Nìgbà tí a bá fẹ́ wọlé

“Nígbà ti ènìyàn bá wọ ilé rẹ̀, kí ó wí pé: {Allāhumma ’innī ’as’aluka khayral-Mawlij, wakhayral-Makhraj, bismillāhi walajnā, wabismillāhi kharajnā, wa‘alā Rabbinā tawakkalnā} (Ìrẹ Ọlọ́hun! Dájúdájú èmi ń tọrọ wíwọlé dáadáa ní ọ̀dọ̀ Rẹ̀, àti jíjáde dáadáa. A wọlé pẹ̀lú Orúkọ Ọlọ́hun; a sì jáde pẹ̀lú Orúkọ Ọlọ́hun, àti pé Ọlọ́hun Allāh, Ọlọ́hun Ọba wa nìkan ni a gbé ara lé). Lẹ́yìn náà kí ó sálámà sí àwọn ará ilé rẹ̀” (Abū Dāwūd: 5096).

 Nìgbà tí a bá fẹ́ jáde nílé

“{Bismillāh, tawakkaltu ‘alallāh, walā ḥawla walā quwwata ’illā billāh. Allāhumma ’innī ’a‘ūdhu bika ’an ’aḍilla ’aw ’uḍall, ’aw ’azilla ’aw ’uzall, ’aw aẓlima ’aw ’uẓlam, ’aw ’ajhala ’aw yujhala ‘alayy} ((Mò ń jáde) pẹ̀lú Orúkọ Ọlọ́hun; mo gbé ara lé Ọlọ́hun, Kò sí ọgbọ́n kan, kò sì sí agbára kan àyàfi pẹ̀lú Ọlọ́hun. Ìrẹ Ọlọ́hun! Dájúdájú èmi ń wá ìṣọ́ pẹ̀lú Rẹ kúrò níbi kí n sọnù; tàbí kí ẹlòmíràn sọ mí nù, tàbí kí n ṣìṣe, tàbí kí ẹlòmíràn mú mi ṣe àṣìṣe, tàbí kí n ṣe àbòsí, tàbí kí ẹlòmíràn ṣe àbòsí fùn mi, tàbí kí n hùwà àìmọ̀kan,  tàbí kí ẹlòmíràn hùwà àìmọ̀kan sí mi) (Abū Dāwūd: 5094-5095).

Àdúrà tí a máa ń ṣe nìgbà tí a bá fẹ́ sùn

Àdúrà tí a máa ń ṣe síwájú oorun

“Bismikallāhumma ’amūtu wa’aḥyā” Pẹ̀lú Orúkọ Rẹ, Ìrẹ Ọlọ́hun, ni màá fi kú, ni màá sì fi ṣẹ̀mí (Al-Bukhārī: 5953, Muslim: 2711)

Àdúrà tí a máa ń ṣe tí a bá jí lójú oorun
{“Al-ḥamdu lillāhil-ladhī ’aḥyānā ba‘da mā ’amātanā wa-’ilayhin-nushūr” Gbogbo ọpẹ́ àti ẹyìn ti Ọlọ́hun ni í ṣe, Ẹni tí Ó sọ wá di alààyè lẹ́yìn ìgbà tí Ó ti gba ẹ̀mí wa, àti pé ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni Ìgbéǹde yóò jẹ́} (Al-Bukhārī: 5953, Muslim: 2711).

Ìrun pípè àti Mọṣáláṣí

A ṣe é ní òfi ẹ̀sìn Mùsùlùmí kí ó máa pààrà ohun tí apèrun ń sọ, àyàfi nígbà tí ó bá wí pé: Ḥayya ‘alaṣ-ṣalāh (ẹ yára wá kírun), tàbí ḥayya ‘alal-falāḥ (ẹ yára wá jèrè), yóò wí pé: Lā ḥawla walā quwwata ’illā billāh (kò sí ọgbọ́n kankan, kò sì sí agbára kankan àyàfi pẹ̀lú Ọlọ́hun).

Lẹ́yìn ìrun pípè yóò wí pé: {Allāhumma Rabba hādhihid-da‘watit-tāmmah, waṣ-ṣalātil-qā’imah ’āti Muḥammadan al-wasīlata wal-faḍīlah, wab‘athhu maqāman maḥmūdanil-ladhī wa‘attah} (Ìrẹ Ọlọ́hun! Ọlọ́hun Ọba tí Ó ni ìpèpè tí ó pé yìí, àti ìrun tí a gbé nàró. Fún Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun Muḥammad ní Al-Wasīlah (ààyè gíga kan nínú ọgbà-ìdẹ̀ra) àti àgbéga (lórí gbogbo ẹ̀dá), sì gbé e dìde ní ààyè ẹyìn eléyìí tí O bá a ṣe àdéhùn). Dájúdájú Ànábí -kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a- dun ẹni tí ó bá sọ èyí nínú pẹ̀lú ọ̀rọ̀ rẹ̀: “Ìṣìpẹ̀ mi yóò di ẹ̀tọ́ fún un” (Al-Bukhārī: 589).     

Nìgbà tí a bá fẹ́ wọ Mọṣáláṣí 

{Bismillāh, waṣ-ṣalātu, was-salāmu ‘alā rasūlillāh, Allāhummaghfir lī dhunūbī waftaḥ lī abwāba raḥmatik}(Mò ń wọlé pẹ̀lú Orúkọ Ọlọ́hun; ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun kí ó máa bá Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun. Ìrẹ Ọlọ́hun! Ṣe àforíjìn àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi fún mi, tún ṣí àwọn ilẹ̀kùn àánú Rẹ fún mi). Nígbà tí ó ń jáde, yóò wí pé: “{Bismillāh waṣ-ṣalātu was-salāmu ‘alā rasūlillāh, Allāhummaftaḥ lī abwāba faḍlik} (Mò ń jáde pẹ̀lú Orúkọ Ọlọ́hun, ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun kí ó máa bá Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun. Ìrẹ Ọlọ́hun! Ṣí àwọn ilẹ̀kùn Ọlá Rẹ fún mi).

Lẹ́yìn ìrun ọ̀ranyàn 

’Astaghfirullāh: (Mò ń tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Ọlọ́hun),  yóó sọ ọ́ ní ẹ̀ẹ̀mẹta. 

(Allāhumma ’Antas-salām waminkas-salām, tabārakta yā dhal-jalāli wal-’ikrām: Ìrẹ Ọlọ́hun! Ìwọ ni Àlááfíà, ọ̀dọ̀ Rẹ sì ni àlááfíà tí ń wá. Ìbùkún ni fún Ọ, Ìrẹ Ọba tí Ó ni títóbi àti àpọ́nlé). (Muslim: 591).

Lẹ́yìn náà yóò ṣe àfọ̀mọ́ fún Ọlọ́hun nígbà 33, yóò wí pé: (Subḥānallāh: Mímọ́ ni fún Ọlọ́hun), yóò yin Ọlọ́hun nígbà 33, yóò wí pé: (Al-ḥamdu lillāh: Gbogbo ọpẹ́ àti ẹyìn tí  Ọlọ́hun  ní í ṣe). Yóò gbé Ọlọ́hun tóbi nígbà 33, yóò wí pé:  (Allāhu ’Akbar: Ọlọ́hun ni Ó tóbi jùlọ). Yóò sì pé ọgọ́rùn-ún pẹ̀lú kí ó wí pé: (Lā ’ilāha ’illallāhu waḥdahu lā sharīka lah, lahul-mulku walahul-ḥamd, wahuwa ‘alā kulli shay’in Qadīr:  Kò sí ọlọ́hun tí ó lẹ́tọ̀ọ́ sí ìjọsìn àyàfi Ọlọ́hun Allāh nìkan ṣoṣo, kò sí orogún fún Un. Ti Ẹ̀ ni ìjọba, ti Ẹ̀ sì ni gbogbo ọpẹ́ àti ẹyìn í ṣe, àti pé Òun ni Alágbára lórí gbogbo nǹkan). (Muslim: 597). 
Dájúdájú Ànábí -kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a- dun ẹni tí ó bá sọ ọ́ nínú pẹ̀lú àforíjìn àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ kódà kí ó tó ìfòfó òkun (Muslim: 597).

Kíké ’Āyatul-Kursiyy (wo: ojú-ewé 271)

Kíké Al-Mu‘awwidhāt  (wo:  ojú-ewé 272)

Ìtọ́ka Mùsùlùmí tí a ṣe ní ìrọ̀rùn

Ààyè Ìtọ́ka Mùsùlùmí tí a ṣe ní ìrọ̀rùn jẹ́ ẹ̀dà orí ẹ̀rọ ayé-lu-jára láti inú ìwé (Ìtọ́ka Mùsùlùmí tí a ṣe ní ìrọ̀rùn). Ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn iṣẹ ilé-iṣẹ́ ìtọ́ka ìgbàlódé. A sì ti tẹ̀ ẹ́ jáde pẹ̀lú èdè tó ju 15 lọ. A tún ti mú àkóónú rẹ̀ wá lórí ọlọ́kan-ò-jọ̀kan nínú àwọn ìkànnì ẹ̀rọ ayé-lu-jára tó yanrannti

Modern Guide