Ìdí tí Ọlọ́hun fi dá wa

×

Error message

Deprecated function: Function create_function() is deprecated in views_php_handler_field->pre_render() (line 202 of /var/www/drupal7-websites/sites/all/modules/contrib/views_php/plugins/views/views_php_handler_field.inc).
man pray in the mosque

Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn oníròrí àti àwọn aláìmòye bákan náà ń bẹ nínú ìrújú nípa ìdáhùn sí ìbéèrè tí ó pàtàkì jùlọ̀ nínú ìṣẹ̀mí ayé wa:

Nítorí kín ni a fi ń bẹ ní ayé? 

Kín gan-an ni à ń torí rẹ̀ ṣẹ̀mí? 

Dájúdájú Al-Qur’ān ti ṣe àdáyanrí ìdí àti èròńgbà tí ń bẹ ní abẹ́ bíbẹ ènìyàn nínú ìṣẹ̀mí ayé yìí pẹ̀lù gbogbo àgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tí ó hàn kedere, tí ó sí kún, nínú ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun, Ọba tí ọlá Rẹ̀ ga, tí Ó sọ wí pé: “Àti pé mi ò dá àwọn àlùjànnú ati àwọn ènìyàn lásán àyàfi nítorí kí wọ́n le máa jọ́sìn fún Mi”{Adh-Dhāriyāt: 56}.

Nítorí náà ìjọsìn fún Ọlọ́hun ni ìdí pàtàkì tí a fi ń bẹ ní orí ilẹ̀ yìí, ohun mìíràn yàtọ̀ sí i kàn jẹ́ àtẹ̀gùn, àsọ́mọgbè àti àfikún lásán ni.

Ṣúgbọ́n ìjọsìn fún Ọlọ́hun nínú àgbọ́yé ẹ̀sìn Islām kì í ṣe ìjọsìn ayé-ò-kàn-mí àti pípa ìṣẹ̀mí ayé, àwọn adùn rẹ̀ àti àwọn ìgbádùn rẹ̀ tì. Ṣúgbọ́n pẹ̀lú ìrun, ààwẹ̀ àti Zakāh yíyọ, ó tún kó gbogbo iṣẹ́ ènìyàn, àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀, àwọn iṣẹ́ àwárí rẹ̀ àti àwọn àjọṣepọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú elòmíràn sínú, kódà tí ó fi dé orí eré rẹ̀ àti ìgbádùn rẹ̀. Ní òpin ìgbà tí àníyàn dáadáa àti èròǹgbà rere bá ti wà pẹ̀lú rẹ̀. Ìdí nì yìí tí Ànábí -kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a- fi sọ wí pé: “Ẹ̀san ìtọrẹ àànú ń bẹ níbi ìbálòpọ̀ ẹnìkan nínú yín pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀” (Muslim 1006). Ìtumọ̀ èyí ni wí pé Mùsùlùmí yóò máa gba ẹ̀san dáadáa títí dé orí ìbálòpọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀.       
Pẹ̀lú èyí, ìjọsìn fún Ọlọ́hun, pẹ̀lú pé ó jẹ́ ìdí ìṣẹ̀mí ayé, yòó tún di: Ojúlówó ìṣẹ̀mí ayé. Nítorí nàá Mùsùlùmí yóò máa pààrá láàrin oríṣirísi àwọn ìjọsìn fún Ọlọ́hun, Gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́hun, Ọba tí ọlá Rẹ̀ ga, ti wí pé: “Wí pé: Dájúdájú ìrun mi, ẹran pípa mi, ìṣẹ̀mí mi àti ikú mi, fún Ọlọ́hun ni, Ọlọ́hun Ọba gbogbo àgbáyé” {Al-’An‘ām: 162}.    

Ìtọ́ka Mùsùlùmí tí a ṣe ní ìrọ̀rùn

Ààyè Ìtọ́ka Mùsùlùmí tí a ṣe ní ìrọ̀rùn jẹ́ ẹ̀dà orí ẹ̀rọ ayé-lu-jára láti inú ìwé (Ìtọ́ka Mùsùlùmí tí a ṣe ní ìrọ̀rùn). Ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn iṣẹ ilé-iṣẹ́ ìtọ́ka ìgbàlódé. A sì ti tẹ̀ ẹ́ jáde pẹ̀lú èdè tó ju 15 lọ. A tún ti mú àkóónú rẹ̀ wá lórí ọlọ́kan-ò-jọ̀kan nínú àwọn ìkànnì ẹ̀rọ ayé-lu-jára tó yanrannti

Modern Guide