Àwọn ààyè tí a ti máa ń fa òfin ẹ̀sìn yọ nínú ẹ̀sìn Islām

×

Error message

Deprecated function: Function create_function() is deprecated in views_php_handler_field->pre_render() (line 202 of /var/www/drupal7-websites/sites/all/modules/contrib/views_php/plugins/views/views_php_handler_field.inc).

Àwọn Mùsùlùm, láti mọ àwọn òfin ẹ̀sìn Islām àti àwọn ìdájọ́ rẹ̀, máa ń gbé ara lé àwọn ìpìlẹ̀ kan àti àwọn ẹ̀rí tí ó tóbi jùlọ. Wọ́n máa ń fa ìmọ̀ nípa ìdájọ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yọ láti ibẹ̀; ṣé ẹ̀tọ́ ni tábí èèwọ̀ ni..    

Àwọn òfin ẹ̀sìn Islām tí ó jẹ́ alákòópọ̀ ni ìwọ̀nyí: 

 1. Al-Qur’ān Alápọ̀n-ọ́nlé:

Òhun ni Tírà Ọlọ́hun, èyí tí Ó sọ̀kalẹ̀ fún àwọn ẹ̀rúsìn Rẹ̀, láti jẹ́ ìmọ̀nà, àlàyé àti  òǹpinyà láàrin òdodo àti ìbàjẹ́. Òhun náà sì ni Ọlọ́hun ṣọ́ kúrò níbi yíyí i padà tàbí pípààrọ̀ rẹ̀. Nítorí náà tí Ọlọ́hun bá pàṣẹ nínú Tírà Rẹ̀ tàbí Ó kọ̀, ọ̀ranyàn ni lórí àwọn Mùsùlùmí láti gbàfà fún ohun tí àṣẹ àti kíkọ̀ náà ń fẹ́ ní ọ̀dọ̀ wọn. Nígbà tí Ọlọ́hun bá wí pé: “Àti pé ẹ máa gbé ìrun nàró” (An-Nūr: 56), a ó mọ̀ dájú pé ọ̀ranyàn ni ìrun kíkí. Nígbà tí Ó bá wí pé: “Ẹ má sì ṣe súnmọ́ àgbàrè. Dájúdájú ohun jẹ́ ìwà ìríra, ò sì jẹ́ ọ̀nà tí ó burúkú jáì” (Al-’Isrā’: 32), a ó mọ̀ dájú pé èèwọ̀ ni àgbèrè ṣíṣe.. Nígbà tí ó sì jẹ́ wí pé dájúdájú Ọlọ́hun fún ara Rẹ̀ tí mójútó ṣíṣọ́ Al-Qur’ān kúrò níbi àyípadà, àfikún àti àdínkù, dájúdájú ohun kan ṣoṣo tí a bùkáátà sí ni kí á fi ẹsẹ̀ rẹ̀ múlẹ̀ pè ẹsẹ (’āyah) Al-Qur’ān tọ́ka sí ohun tí a fẹ́ lò ó fún.     

 1. Ìlànà Ànábì: 

Òhun ni gbogbo ohun tí ó bá fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú àwọn ọ̀rọ̀ Ànábì -kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a-, àwọn ìṣe rẹ̀, ohun tí wọ́n ṣe ní ojú rẹ̀ tí kò sì takò ó àti àwọn ìhùwàsí rẹ̀. Nígbà tí a bá ti mọ̀ pé ọ̀rọ̀ Ànábì -kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a- fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ pé: “A kì í fẹ́ obìnrin àti arábìnrin bàbá rẹ̀ papọ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni obìnrin àti arábìnrin ìyá rẹ̀” (Al-Bukhārī: 5109), a ó mọ̀ pé kò ní ẹ̀tọ́, kò sì ní àlááfíà, kí ọkùnrin fẹ́ obìnrin, kí ó tún wá fẹ́ arábìnrin bàbá rẹ̀, tàbí arábìnrin ìyá rẹ̀ mọ́ ọn.  

A máa ń wòye sí ìlànà Ànábì -kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a-, láti fa àwọn ìdájọ́ ẹ̀sìn yọ nínú rẹ̀, ní ọ̀nà méjì:

 • Fífi ẹsẹ̀ múlẹ̀ Ḥadīth dé ọ̀dọ̀ Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun -kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a-. Àwọn Àlùfáà ẹ̀sìn Islām tí ṣe àwọn ìgbìyànjú tí ó ní agbára, wọ́n sì ti ṣe àgbékalẹ̀ àwọn òǹdè àwòjinlẹ̀ àti àmọ̀dájú nípa ṣíṣe àgbéyẹ̀wò ìlànà Ànábì tí ó biyì, àti nípa ṣíṣe àdáyanrí Ḥadīth tí ó ní àlááfíà, èyí tí ó fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀gbàwá àwọn ẹni tí ó ṣe fi ọkàn tán, tí wọ́n sì mọ nǹkan há dáadáa, yàtọ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ tí àwọn kan fi tì sí Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun -kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a-, tí kò sí nínú ìlànà rẹ̀, èyí tí ó ṣe pé àṣìṣe àti àìṣe àkíyèsí ní ó ṣe okùnfà rẹ̀, tàbí látara irọ́ apákan àwọn ọ̀tá ẹ̀sìn Islām.   
 • Títọ́ka Ḥadīth sí ìtumọ̀ tí a fẹ́ lò ó fún,  ìtọ́ka yìí le jẹ́ ohun tí ó lọ sàn án, tí ó sì  hàn kedere, tí kò sì ìyapa-ẹnu nípa ìtumọ̀ rẹ̀. Ó sì tún le kò ìtumọ̀ tí ó pọ̀ sínú, tàbí kí ó jẹ́ wí pé a ò le dá a gbọ́yé àyàfi kí á dà á pọ̀ mọ́ Ḥadīth mìíràn. 
 1. Ìpanupọ̀ àwọn Àlùfáà ẹ̀sìn Islām:

Èyí ni ìpanupọ̀ gbogbo àwọn Àlùfáà ẹ̀sìn Islām pátá lórí ọ̀ràn kan ní èyíkéyìí nínú àwọn àsìkò. Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ìdájọ́ ẹ̀sìn Islām àti àwọn òfin rẹ̀ tí ó tóbi jùlọ ní àwọn Àlùfáà ẹ̀sìn Islām panupọ̀ lórí rẹ̀, wọn kò sì yapa ẹnu lórí rẹ̀. Nínú rẹ̀ ni: Iye òǹkà òpó (rak‘ah) ìrun, àsìkò ìkó-ẹnu ró nínú ààwẹ̀ àti àsìkò ìṣínu, òduwọ̀n iye Zakah nínú wúrà àti fàdákà, àti àwọn ìdájọ́ mìíràn. 

Nígbà tí àwọn sàábé tàbí àwọn tí ó wá lẹ́yìn wọn bá ti panupọ̀ lórí ọ̀rọ̀ kan, ìyẹn jẹ́ ẹ̀rí pé ó ní àlááfíà; nítorí pé gbogbo ìjọ Mùsùlùmí páta kò le panupọ̀ lórí àṣìṣe.

 1. Fífi nńkan wé nǹkan:

Òhun ni gbígbé ìdájọ́ lórí ọ̀ràn kan tí kò wá nínú Tírà Ọlọ́hun àti ìlànà Ànábí pẹ̀lú ìdájọ́ ọ̀ràn mìíràn tí òhun wá nínú àwọn méjèèjì, nítorí pé àwọn méjèèjì papọ̀ níbi ìdí àti sábàbí ìdájọ́ náà. Gẹ́gẹ́ bíi gbólóhùn wa pé èèwọ̀ ni nína òbí ẹni méjèèjì ní àfiwé sí jíjẹ́ èèwọ̀ ṣíṣe ṣíọ̀ sí wọn àti jíjágbe mọ́ wọn. Gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́hun, Ọba tí ọlá Rẹ̀ ga, ti wí pé: “Má ṣe sọ ọ̀rọ̀ àbùkù sí wọn, má sì ṣe jágbe mọ́ wọn” (Al-’Isrā’: 23). Tí ó bá jẹ́ wí pé Ọlọ́hun ṣe jíjágbe mọ́ wọn ní èèwọ̀ nítorí kí á má ṣe fi ṣùtà kan àwọn òbí wa méjèèjì, a jẹ́ wí pé èèwọ̀ ni nínà wọ́n ní ọ̀nà tí ó burúkú jùlọ nítorí pé àwọn méjèèjì papọ̀ níbi fífi ṣùtà kan wọ́n. Èyí jẹ́ ọ̀nà kan tí ó jindò, àwọn àgbà-ọ̀jẹ̀ onímímọ̀ nípa ẹ̀sìn nìkan ní wọ́n le dá sí i. Pẹ̀lú rẹ̀ ni a sì fi máa ń mọ ìdájọ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ titun.   

Kín ni ó fà á tí àwọn Àlùfáà fi máa ń yapa ẹnu, tí ó sì jẹ́ wí pé ẹnu wọn kò lórí àwọn ààyè tí a ti máa ń fa òfin ẹ̀sìn Islām yọ?

Láti mọ èyí, ó ṣe ọ̀ranyàn kí o mọ ohun tí ó ń bọ̀ yìí: 

 1.  Gbogbo àwọn Àlùfáà ẹ̀sìn Islām panupọ̀ lórí àwọn ohun tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìgbàgbọ́ òdodo, àwọn ìpìlẹ̀ òfin ẹ̀sìn Islām, àwọn orígun ẹ̀sìn Islām àti àwọn òpó rẹ̀ tí ó tóbi. Ìwọ̀n-ǹba ìyapa ẹnu wọn lórí apákan àlàyé nípa àwọn ìdájọ́ àgbọ́yé ẹ̀sìn Islām àti bí a ó ti lò ó nìkan ni.

Ṣùgbọ́n àwọn òpó gbogbo gbò, àti ìpìlẹ̀  àwọn ìdájọ́, àwọn Àlùfáà ẹ̀sìn Islām panupọ̀ lórí rẹ̀ pẹ̀lú ọlá Ọlọ́hun lórí òfin ẹ̀sìn Islām yìí, èyí tí ó jẹ́ wí pé òhun ni òpin àwọn òfin ẹ̀sìn àti iṣẹ́-rírán. Èyí tí Ọlọ́hun fún ara Rẹ̀ ń mójútó ṣíṣọ́ rẹ̀ títí tí Ọlọ́hun yóò fi jogún ilẹ̀ àti gbogbo ohun tí ń bẹ lórí rẹ̀.  

 1.  Yíyapa ẹnu nípa àwọn ohun tí ó jẹ́ ẹka àti lórí àlàyé jẹ́ àdàmọ́ ènìyàn.  Kò sí òfin ẹ̀sìn kankan tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́hun tàbí tí ó jẹ́ àtọwọ́dá àwọn ènìyàn tí ó là kúrò nínú èyí. Àwọn amòfin máa ń yapa ẹnu lórí àlàyé òfin, àwọn ilé-ẹjọ́ máa ń yapa ẹnu nípa mímú un lò, àwọn akọ̀tàn máa ń yapa ẹnu nípa àwọn ẹ̀gbàwá àti ìṣẹ̀lẹ̀ rẹ̀, àwọn dókítà, àwọn onímọ́-ẹ̀rọ, àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ àti àwọn onímọ́-ìjìnlẹ̀ náà máa yapa ẹnu nípa àkòrí ọ̀rọ̀ kan ṣoṣo, nípa wíwòye sí i àti nípa wíwá ojútùú sí i.    

Nítorí náà yíyapa ẹnu nípa àwọn ohun tí ó jẹ́ ẹka àti lórí àlàyé jẹ́ àdàmọ́ ènìyàn, ìṣẹ̀mí wíwá ìmọ̀ àti iṣẹ́ pèpè fún un.

 1.  Dájúdájú Ọlọ́hun, Ọba Abiyì, tí Ó gbọn-n-gbọ́n,  ti ṣe àmójúkúró fún ẹni tí ó bá gba ọ̀nà tí ó ní àlááfíà wá òdodo, ṣùgbọ́n tí ó ṣe àṣìṣe láti dé ibẹ̀. Àti pé dájúdájú Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun -kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a-, ti fún ẹni tí ó bá gba ọ̀nà tí ó ní àlááfíà wádìí nípa òdodo ní ìró ìdùnnú pé ẹ̀san rere kò ní bọ́ mọ́ ọn lọ́wọ́ níbi ìṣesí méjèèjè (bóyá ó ṣe déédé tàbí ó ṣe àṣìṣe).

Tí ó bá ṣe déédé òdodo, yóò gba ẹ̀san rere méjì. Ṣùgbọ́n tí ó bá ṣe àṣìṣe pẹ̀lù ojú-kòkòrò rẹ̀ àti títọ ọ̀nà tí ó ní àlááfíà rẹ̀, yóò gba ẹ̀san rere kan. Ànábí -kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a- sọ wí pé: “Tí adájọ́ bá dájọ́, tí ó sì gbìyànjú, lẹ́yìn náà tí ìdájọ́ rẹ̀ ṣe déédé, yóò gba ẹ̀san rere méjì, ṣùgbọ́n tí ó bá dájọ́, tí ó sì gbìyànjú, lẹ́yìn náà tí ó wá ṣe àṣìṣe, yóò gba ẹ̀san rere kan” (Al-Bukhārī: 7352).

Nígbà tí Ọlọ́hun ń sọ̀rọ̀ nípa ìtàn àwọn Ànábí Rẹ̀; Dāwūd àti Sulaymān -kí  ọlà Ọlọ́hun máa bá àwọn méjèèjì-, nígbà tí wọ́n kó ọ̀ràn kan wá bá àwọn méjèèjì láti dájọ́ nípa rẹ̀, àwọn méjèèjì jọjọ gbìyànjú, Sulaymān -kí  ọlà Ọlọ́hun máa bá a-, dá ẹjọ́ tí ó ṣe déédé, ṣùgbọ́n Ọlọ́hun kò fi Dāwūd -kí  ọlà Ọlọ́hun máa bá a-, ṣe kòǹgẹ́ níbi ìdájọ́ náà. Ọlọ́hun fi níní àlááfíà ọ̀rọ̀ Sulaymān àti àṣìṣe Dāwūd -kí ọlà Ọlọ́hun máa bá àwọn méjèèjì- rinlẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀ Ọlọ́hun ṣe ẹyìn fún ìmọ̀ àwọn méjèèjì lápapọ̀, gẹ́gẹ́ bí Ó ti wí pé: “Àti pé A jẹ́ kí Sulaymān gbọ́ ọ yé, kálukú ni A sì fún ní ìdájọ́ (òdodo àti ìjẹ́-Òjíṣẹ́) àti ìmọ̀” (Al-’Anbiyā’: 79)

 1. Gbogbo àwọn Àlùfáà ẹ̀sìn Islām àti àwọn Imām mẹ́rẹ̀ẹ̀rin máa ń gbé ara lé Tírà Ọlọ́hun àti ìlànà Ànábì. Wọn kì í ti ìròrí tàbí àtakò kankan síwájú rẹ̀. Wọn kì í ti ìròrí tàbí àtakò kankan síwájú rẹ̀. Ìyapa ẹnu wọn kò dá lórí ìfẹ́-inú tàbí nítorí èróńgbà ti ara wọn tàbí àǹfààní tí wọ́n ń wá. Ṣùgbọ́n ó dá lórí àwọn ìpìlẹ̀ ìmọ̀ tí ó ní àkòrí, tí ó wà fún mímọ òdodo. Nígbà míràn ẹ̀gbàwá Ḥadīth yóò dé ọ̀dọ̀ ọ̀kan nínú àwọn Àlùfáà ẹ̀sìn Islām, kò sì ní dé ọ̀dọ̀ òmíràn, tàbí kí fífi ìmọ̀ wòye wọn sí àgbọ́yé ẹ̀rí láti inú Tírà Ọlọ́hun àti ìlànà Ànábì yapa sí ara wọn, àti àwọn ìdí mìíràn.   

Àwọn mẹ́rin gbajúmọ̀ nínú àwọn Àlùfáà tí ó pàtàkì jùlọ àti àwọn onímímọ̀ nípa àgbọ́yé ẹ̀sìn Islām, àwọn ènìyàn sì panupọ̀ lórí jíjẹ́ asiwájú wọn níbi ìmọ̀ àti ẹ̀sìn. Wọ́n dé ipò tí ó ga nínú àgbọ́yé ẹ̀sìn Islām, ìmọ̀ àti ṣíṣe ẹ̀sìn. Àwọn ọmọ-akẹ́kọ̀ọ́ wọn pọ̀, wọ́n sì fọ́n ọ̀rọ̀ wọn (nípa ẹ̀sìn Islām) ká, wọ́n sì tún fi kọ́ àwọn ènìyàn káàkiri orí ilẹ̀. Nítorí náà a ní ilé-ẹ̀kọ́ àgbọ́yé ẹ̀sìn Islām mẹ́rin, èyí tí ó tàn ká ìlú àwọn Mùsùlùmí tí a ṣe àfitì rẹ̀ sí wọn, àwọn nìyí:   

 • Al-Imām Abū Ḥanīfah, orúkọ rẹ̀ ni An-Nu‘mān ọmọ Thābit. Ó ṣẹ̀mì ní ‘Irāq, ó sì kú ní ọdún 150 lẹ́yìn Hijrah Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun. Ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni a máa ń fi ilé-ẹ̀kọ́ Ḥanafī  tì sí. 
 • اAl-Imām Mālik ọmọ ’Anas Al-’Aṣbaḥī, Imām ìlú Madīnah oní-ìmọ́lẹ̀, ó kú ní ọdún 179 lẹ́yìn Hijrah Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun.  Ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni a máa ń fi ilé-ẹ̀kọ́ Mālikī  tì sí. 
 •  Al-Imām Ash-Shāfi‘ī, orúkọ rẹ̀ ni Muḥammad ọmọ Idrīs. Ó ṣẹ̀mì ní ààrin ìlú Makkah, Madīnah, ‘Irāq àti Miṣr. Ó sì kú ní ọdún 204 lẹ́yìn Hijrah Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun.  Ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni a máa ń fi ilé-ẹ̀kọ́ Ash-Shāfi‘ī  tì sí. 
 • Al-Imām Aḥmad ọmọ Ḥanbal, ó lo ọ̀pọ̀ nínú ìṣẹ̀mì ní ‘Irāq, ó sì kú ní ọdún 241 lẹ́yìn Hijrah Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun. Ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni a máa ń fi ilé-ẹ̀kọ́ Ḥanbalī  tì sí.

Jíjọjọ máa ṣe ẹyìn fún ara ẹni wáyé láàrin àwọn Imām mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àti àwọn ọmọ-akẹ́kọ̀ọ́ wọn, bẹ́ẹ̀ náà ni oríṣiríṣi ìjomitoro ìmọ̀. Kálukú wọn ni ó ń ṣe ojúkòkòrò láti tẹ̀lé òdodo àti ohun tí ó ṣe déédé, tí kò sì rí aburú níbi kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ bá ti lágbájá mu níbi ọ̀ràn kan tàbí kí  ó bá ti tàmẹ̀dò mu níbi òmíràn, nítorí títẹ̀lé òdodo àti ẹ̀rí. Èyí ni ó fà á, tí a ó fi rí i pé, apákan wọn kọ́ ẹ̀kọ́ ní ọ̀dọ̀ apákejì. Al-Imām Aḥmad (ní àpèjúwe) kọ́ ẹ̀kọ́ ní ọ̀dọ̀ Ash-Shāfi‘ī, Ash-Shāfi‘ī náà kọ́ ẹ̀kọ́ ní ọ̀dọ̀ Al-Imām Mālik. Àwọn ọ̀kan-ò-jọ̀kan ìpàdé àti ìjomitoro ìmọ̀ ni ó wáyé láàrin Al-Imām Mālik àti àwọn ọmọ-akẹ́kọ̀ọ́ Abū Ḥanīfah.     

Dájúdájú ó ti fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn Imām mẹ́rẹ̀ẹ̀rin; ọ̀rọ̀ wọn pé: Tí ẹ̀gbàwá Ḥadīth bá ti ní àlááfíà, òhun gan-an ní ìlànà mi. Èróńgbà wọn àkọ́kọ́ ni fífọ́n ìmọ̀ ká àti gbígbé àìmọ̀kan kúrò fún àwọn ènìyàn. Kí Ọlọ́hun ṣe ìkẹ́ tí ó gbààyè fún wọn.

Kín ni ó ṣe ọ̀ranyàn lórí Mùsùlùmí nípa ìyapa-ẹnu níbi àgbọ́yé ẹ̀sìn?

Ohun ti ó ṣe ọ̀ranyàn lórí Mùsùlùmí ni kí ó gbìyànjú nípa títẹ̀lé òdodo àti nípa mímọ̀ ọ́n…

 • Tí ó bá wà nínú àwọn ọmọ-akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n ti jindò níbi ọ̀nà ìmọ̀ kan, tí wọ́n sì káátò láti ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ẹ̀rí, ó ṣe ọ̀ranyàn fún un kí ó tẹ̀lé ohun tí ìgbìyànjú rẹ̀ bá dé níbi àgbọ́yé àwọn ẹ̀rí, ní ìbámu sí àwọn àgbékalẹ̀ òfin ìmọ̀ ìpìlẹ̀ àgbọ́yé ẹ̀sìn. Ṣùgbọ́n ó jẹ́ èèwọ̀ fún un kí ó ṣègbè lẹ́yìn Àlùfáà rẹ̀ tàbí ilé-ẹ̀kọ́ Imām rẹ̀ nígbà tí ó bá hàn sí i pé ọ̀dọ̀ ẹlòmíràn ni òdodo wà.     
 • Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá wà nínú ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn Mùsùlùmí, tí kì í ṣe ẹni tí ó jindò níbi ọ̀nà ìmọ̀ kan tàbí ẹni tí ó káátò láti wòye sí àwọn ẹ̀rí, ó ṣe ọ̀ranyàn fún un nígbà náà, kí ó tẹ̀lé ẹni tí ọkàn rẹ̀ balẹ̀ sí jùlọ níbi ẹ̀sìn àti ìmọ̀ rẹ̀. Pẹ̀lú èyí, ó ti ṣe ohun tí ó jẹ́ ọ̀ranyàn lórí rẹ̀, ó sì ti ṣe àmúlò ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun, Ọba tí ọlá Rẹ̀ ga, tí Ó sọ pé: “Nítorí náà ẹ bi àwọn oní ìrántí (àwọn oní tírà tí wọ́n ti síwájú) léèrè, tí ó bá ṣepé ẹ kò mọ̀” {Al-’Anbiyā’: 7}.   

Tí ó bá mọ ọ̀rọ̀ kan tí ó ṣe é gbára lé (nínú ẹ̀sìn) tàbí ó bi Àlùfáà ẹ̀sìn tí ó káátò léèrè nípa ọ̀ràn kan, kì í ṣe ọ̀ranyàn ni fún un kí ó tún bi ẹlòmíràn léèrè lẹ́yìn rẹ̀. Tí ó bá padà mọ ọ̀rọ̀ mìíràn tí ó yapa rẹ̀, ó ṣe ọ̀ranyàn fún un nígbà náà, kí ó tẹ̀lé ẹni tí ó bá rò pé òun ni ó súnmọ́ déédé àti òdodo jùlọ. Gẹ́gẹ́ bí aláìsàn tí máa ń ṣe nígbà tí ìmọ̀ràn àwọn dókítà nípa ìwòsàn ohun tí ó ń ṣe é bá yapa ara wọn.      

Ó tún ṣe ọ̀ranyàn fún un kí ó má ṣe tàbùkù tàbí ṣe àtakò ẹlòmíràn nínú àwọn Mùsùlùmí nígbà tí ó bá yapa rẹ̀ níbi ìròrí, ní òpin ìgbà tí ó bá jẹ́ wí pé ilé-ẹ̀kọ́ àgbọ́yé ẹ̀sìn kan ní ó tẹ̀lé tàbí ó tẹ̀lé Àlùfáà ẹ̀sìn tí ó káátò tàbí ó wá nínú àwọn ẹni tí ó le dá ìgbìyànjú ṣe, tí ó ní ìmọ̀ nípa àgbọ́yé ẹ̀sìn Islām. Dájúdájú àwọn sàábé àti àwọn ẹni ìsiwájú rere máa ń yapa ẹnu nípa àwọn ọ̀ràn àgbọ́yé ẹ̀sìn Islām, ìfẹ́ àti ìjẹ́-ọmọ-ìyá sí tún ń bẹ láàrin wọn, wọ́n sì máa ń ṣe ìtàkorọ̀sọ láìsí pé apákan ń tàbùkù apákejì.    

Ìtọ́ka Mùsùlùmí tí a ṣe ní ìrọ̀rùn

Ààyè Ìtọ́ka Mùsùlùmí tí a ṣe ní ìrọ̀rùn jẹ́ ẹ̀dà orí ẹ̀rọ ayé-lu-jára láti inú ìwé (Ìtọ́ka Mùsùlùmí tí a ṣe ní ìrọ̀rùn). Ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn iṣẹ ilé-iṣẹ́ ìtọ́ka ìgbàlódé. A sì ti tẹ̀ ẹ́ jáde pẹ̀lú èdè tó ju 15 lọ. A tún ti mú àkóónú rẹ̀ wá lórí ọlọ́kan-ò-jọ̀kan nínú àwọn ìkànnì ẹ̀rọ ayé-lu-jára tó yanrannti

Modern Guide